Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 36:11-20 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Àwọn ọmọ Elifasi ni: Temani, Omari, Sefo, Gatamu ati Kenasi.

12. (Elifasi, ọmọ Esau ní obinrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Timna, òun ni ó bí Amaleki fún un.) Àwọn ni àwọn ọmọ Ada, aya Esau.

13. Àwọn ọmọ Reueli ni Nahati, Sera, Ṣama, ati Misa. Àwọn ni àwọn ọmọ Basemati, aya Esau.

14. Àwọn ọmọ tí Oholibama, ọmọ Ana, ọmọ Sibeoni, aya Esau, bí fún un ni Jeuṣi, Jalamu ati Kora.

15. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ninu àwọn ọmọ Esau nìwọ̀nyí, Lára àwọn ọmọ Elifasi, àkọ́bí Esau, tí Ada bí fún un: Temani, Omari, Sefo, Kenasi.

16. Kora, Gatamu, ati Amaleki. Àwọn wọnyii jẹ́ ọmọ Ada, aya Esau.

17. Lára àwọn ọmọ Reueli, ọmọ Esau, àwọn tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ni: Nahati, Sera, Ṣama, ati Misa. Àwọn ni ìjòyè tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Reueli, ní ilẹ̀ Edomu, wọ́n sì jẹ́ ọmọ Basemati, aya Esau.

18. Lára àwọn ọmọ Oholibama, aya Esau: àwọn tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ni: Jeuṣi, Jalamu, ati Kora. Àwọn ni ìjòyè tí wọ́n ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Oholibama, ọmọ Ana, aya Esau.

19. Wọ́n jẹ́ ọmọ Esau, tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Edomu, àwọn sì ni ìjòyè tí wọ́n ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣẹ̀.

20. Àwọn ọmọ Seiri ará Hori, tí ń gbé ilẹ̀ náà nìyí: àwọn ọmọ rẹ̀ ni: Lotani, Ṣobali, Sibeoni ati Ana,

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 36