Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 34:5-17 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Jakọbu ti gbọ́ pé ó ti ba Dina, ọmọ rẹ̀ jẹ́, ṣugbọn àwọn ọmọ rẹ̀ wà pẹlu àwọn ẹran ninu pápá, Jakọbu kò sọ nǹkankan títí tí wọ́n fi dé.

6. Hamori baba Ṣekemu tọ Jakọbu wá láti bá a sọ̀rọ̀.

7. Nígbà tí àwọn ọmọ Jakọbu pada dé sílé, tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, inú bí wọn gidigidi nítorí bíbá tí Ṣekemu bá Dina lòpọ̀ pẹlu ipá yìí jẹ́ ìwà àbùkù gbáà ní Israẹli, irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò tọ́ sí ẹnikẹ́ni láti hù.

8. Ṣugbọn Hamori bá wọn sọ̀rọ̀, ó ní, “Ọkàn Ṣekemu, ọmọ mi, fà sí arabinrin yín, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fún un kí ó fi ṣe aya.

9. Ẹ jẹ́ kí á jọ máa fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ ara wa, ẹ máa fi àwọn ọmọbinrin yín fún wa, kí àwa náà máa fi àwọn ọmọbinrin wa fún yín.

10. A óo jọ máa gbé pọ̀, ibi tí ó bá wù yín ni ẹ lè gbé, ibi tí ẹ bá fẹ́ ni ẹ ti lè ṣòwò, tí ẹ sì lè ní ohun ìní.”

11. Ṣekemu tún wí fún baba ati àwọn arakunrin omidan náà pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ yọ́nú sí mi, ohunkohun tí ẹ bá ní kí n san, n óo san án.

12. Iyekíye tí ó bá wù yín ni kí ẹ bèèrè fún owó orí iyawo, n óo san án, ẹ ṣá ti fi omidan náà fún mi.”

13. Ọgbọ́n ẹ̀tàn ni àwọn ọmọ Jakọbu fi dá Ṣekemu ati Hamori, baba rẹ̀ lóhùn, nítorí bíbà tí ó ba Dina, arabinrin wọn jẹ́.

14. Wọ́n wí fún wọn pé, “Ìtìjú gbáà ni ó jẹ́, pé kí a fi ọmọbinrin wa fún ẹni tí kò kọlà abẹ́, a kò gbọdọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ rárá.

15. Ohun kan ṣoṣo tí ó lè mú kí ọ̀rọ̀ náà ṣeéṣe ni pé kí ẹ̀yin náà dàbí wa, kí gbogbo ọkunrin yín kọlà abẹ́.

16. Nígbà náà ni a óo tó máa fi ọmọ wa fun yín tí àwa náà yóo máa fẹ́ ọmọ yín, a óo máa gbé pọ̀ pẹlu yín, a óo sì di ọ̀kan.

17. Ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò gbà láti kọlà abẹ́, a óo mú ọmọbinrin wa, a óo sì máa lọ.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 34