Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 32:12-21 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ìwọ ni o ṣá sọ fún mi pé, ‘Ire ni n óo ṣe fún ọ, n óo sì sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ bí iyanrìn etí òkun tí ẹnikẹ́ni kò ní lè kà tán.’ ”

13. Ó sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà, ó sì mú ninu ohun ìní rẹ̀ láti fi ṣe ẹ̀bùn fún Esau arakunrin rẹ̀.

14. Ó ṣa igba (200) ewúrẹ́ ati ogún òbúkọ, igba (200) aguntan, ati ogún àgbò,

15. ọgbọ̀n abo ràkúnmí, tàwọn tọmọ wọn, ogoji abo mààlúù ati akọ mààlúù mẹ́wàá, ogún abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati akọ mẹ́wàá.

16. Ó fi iranṣẹ kọ̀ọ̀kan ṣe olùtọ́jú agbo ẹran kọ̀ọ̀kan. Ó sọ fún àwọn iranṣẹ wọnyi pé, “Ẹ máa lọ ṣáájú mi, kí ẹ sì jẹ́ kí àlàfo wà láàrin agbo ẹran kan ati ekeji.”

17. Ó sọ fún èyí tí ó ṣáájú patapata pé, “Nígbà tí Esau arakunrin mi bá pàdé rẹ, tí ó sì bi ọ́ pé, ‘Ti ta ni ìwọ í ṣe? Níbo ni ò ń lọ? Ta ló sì ni àwọn ẹran tí wọ́n wà níwájú rẹ?’

18. Kí o wí pé, ‘Ti Jakọbu iranṣẹ rẹ ni, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀bùn tí ó fi ranṣẹ sí Esau oluwa rẹ̀, òun alára ń bọ̀ lẹ́yìn.’ ”

19. Bákan náà ni ó kọ́ ekeji ati ẹkẹta ati gbogbo àwọn iranṣẹ tí wọ́n tẹ̀lé àwọn agbo ẹran náà. Ó ní, “Nǹkan kan náà ni kí ẹ máa wí fún Esau, nígbà tí ẹ bá pàdé rẹ̀.

20. Kí ẹ sì wí pé, ‘Jakọbu alára ń bọ̀ lẹ́yìn.’ ” Nítorí ó rò ninu ara rẹ̀ pé, bóyá òun lè fi àwọn ẹ̀bùn tí ó tì ṣáájú wọnyi tù ú lójú, àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, nígbà tí ojú àwọn mejeeji bá pàdé, bóyá yóo dáríjì òun.

21. Nítorí náà, àwọn ẹ̀bùn ni ó kọ́ lọ ṣáájú rẹ̀, òun pàápàá sì dúró ninu àgọ́ ní alẹ́ ọjọ́ náà.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 32