Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 31:47-55 BIBELI MIMỌ (BM)

47. Labani sọ ibẹ̀ ní Jegari Sahaduta, ṣugbọn Jakọbu pè é ní Galeedi.

48. Labani wí pé, “Òkítì yìí ni ohun ẹ̀rí láàrin èmi pẹlu rẹ lónìí.” Nítorí náà ó sọ ọ́ ní Galeedi.

49. Ó sì sọ ọ̀wọ̀n náà ní Misipa, nítorí ó wí pé, “Kí OLUWA ṣọ́ wa nígbà tí a bá pínyà lọ́dọ̀ ara wa.

50. Bí o bá fi ìyà jẹ àwọn ọmọbinrin mi, tabi o tún fẹ́ obinrin mìíràn kún àwọn ọmọbinrin mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹnìkan pẹlu wa, ranti o, Ọlọrun ni ẹlẹ́rìí láàrin àwa mejeeji.”

51. Labani bá sọ fún Jakọbu pé, “Wo òkítì ati ọ̀wọ̀n yìí, tí mo ti gbé kalẹ̀ láàrin àwa mejeeji.

52. Òkítì yìí ati ọ̀wọ̀n yìí sì ni ẹ̀rí pẹlu pé n kò ní kọjá òkítì yìí láti wá gbógun tì ọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ìwọ náà kò ní kọjá òkítì ati ọ̀wọ̀n yìí láti wá gbógun tì mí.

53. Ọlọrun Abrahamu ati Ọlọrun Nahori, àní, Ọlọrun baba wọn ni onídàájọ́ láàrin wa.” Jakọbu náà bá búra ní orúkọ Ọlọrun tí Isaaki baba rẹ̀ ń sìn tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù.

54. Jakọbu bá rúbọ lórí òkè náà, ó pe àwọn ìbátan rẹ̀ láti jẹun, wọ́n sì wà lórí òkè náà ní gbogbo òru ọjọ́ náà.

55. Ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, Labani fi ẹnu ko àwọn ọmọbinrin rẹ̀ ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ lẹ́nu láti dágbére fún wọn, ó súre fún wọn, ó sì pada sílé.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 31