Rakẹli ni ó kó àwọn ère oriṣa náà, ó dì wọ́n sinu àpò gàárì ràkúnmí, ó sì jókòó lé e mọ́lẹ̀. Labani tú gbogbo inú àgọ́ rẹ̀, ṣugbọn kò rí wọn.