Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 31:10-20 BIBELI MIMỌ (BM)

10. “Ní àkókò tí àwọn ẹran náà ń gùn, mo rí i lójú àlá pé àwọn òbúkọ tí wọn ń gun àwọn ẹran jẹ́ àwọn tí àwọ̀ wọn dàbí ti adíkálà ati àwọn onífunfun tóótòòtóó ati àwọn abilà.

11. Angẹli Ọlọrun bá sọ fún mi ní ojú àlá náà, ó ní, ‘Jakọbu.’ Mo dáhùn pé, ‘Èmi nìyí.’

12. Angẹli Ọlọrun bá sọ pé, ‘Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò ó pé gbogbo àwọn òbúkọ tí ó ń gun àwọn ẹran inú agbo jẹ́ aláwọ̀ adíkálà ati onífunfun tóótòòtóó ati abilà, nítorí mo ti rí gbogbo ohun tí Labani ń ṣe sí ọ.

13. Èmi ni Ọlọrun Bẹtẹli, níbi tí o ti ta òróró sórí òkúta tí o sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún mi. Dìde nisinsinyii, kí o jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí, kí o sì pada sí ilẹ̀ tí wọ́n gbé bí ọ.’ ”

14. Ni Rakẹli ati Lea bá dá a lóhùn pé, “Ǹjẹ́ ogún kan tilẹ̀ tún kù fún wa ní ilé baba wa mọ́?

15. Ǹjẹ́ kò ti kà wá kún àjèjì? Nítorí pé ó ti tà wá, ó sì ti ná owó tí ó gbà lórí wa tán.

16. Ti àwa ati àwọn ọmọ wa ni ohun ìní gbogbo tí Ọlọrun gbà lọ́wọ́ baba wa jẹ́, nítorí náà, gbogbo ohun tí Ọlọrun bá sọ fún ọ láti ṣe, ṣe é.”

17. Jakọbu bá dìde, ó gbé àwọn ọmọ ati àwọn aya rẹ̀ gun ràkúnmí.

18. Ó bẹ̀rẹ̀ sí da gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tí ó ti kó jọ ní Padani-aramu siwaju, ó ń pada lọ sọ́dọ̀ Isaaki baba rẹ̀ ní ilẹ̀ Kenaani.

19. Ní àkókò yìí, Labani wà níbi tí ó ti ń gé irun àwọn aguntan rẹ̀, Rakẹli bá jí àwọn ère oriṣa ilé baba rẹ̀ kó.

20. Ọgbọ́n ni Jakọbu lò fún Labani ará Aramea, nítorí pé Jakọbu kò sọ fún un pé òun fẹ́ sálọ.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 31