Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 30:5-22 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Biliha lóyún, ó bí ọmọkunrin kan fún Jakọbu.

6. Rakẹli bá sọ pé, “Ọlọrun dá mi láre, ó gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi, ó sì fún mi ní ọmọkunrin kan.” Nítorí náà, ó sọ ọmọ náà ní Dani.

7. Biliha, iranṣẹbinrin Rakẹli tún lóyún, ó bí ọmọkunrin keji fún Jakọbu.

8. Rakẹli bá sọ pé, “Ìjàkadì gidi ni mo bá ẹ̀gbọ́n mi jà, mo sì ṣẹgun,” ó sì sọ ọmọ náà ní Nafutali.

9. Nígbà tí Lea rí i pé òun kò bímọ mọ́, ó fún Jakọbu ní Silipa, iranṣẹbinrin rẹ̀, kí ó fi ṣe aya.

10. Iranṣẹbinrin Lea bí ọmọkunrin kan fún Jakọbu.

11. Lea bá sọ pé, “Oríire.” Ó bá sọ ọmọ náà ní Gadi.

12. Iranṣẹbinrin Lea tún bí ọmọkunrin mìíràn fún Jakọbu.

13. Lea bá ní, “Mo láyọ̀, nítorí pé àwọn obinrin yóo máa pè mí ní Ẹni-Ayọ̀,” nítorí náà ó sọ ọmọ náà ní Aṣeri.

14. Ní àkókò ìkórè ọkà alikama, Reubẹni bá wọn lọ sí oko, ó sì já èso mandiraki bọ̀ fún Lea ìyá rẹ̀. Nígbà tí Rakẹli rí i, ó bẹ Lea pé kí ó fún òun ninu èso mandiraki ọmọ rẹ̀.

15. Ṣugbọn Lea dá a lóhùn pé, “O gba ọkọ mọ́ mi lọ́wọ́, kò tó ọ, o tún fẹ́ gba èso mandiraki ọmọ mi lọ́wọ́ mi?” Rakẹli bá dá a lóhùn, ó ní: “Bí o bá fún mi ninu èso mandiraki ọmọ rẹ, ọ̀dọ̀ rẹ ni Jakọbu yóo sùn lálẹ́ òní.”

16. Ní ìrọ̀lẹ́, nígbà tí Jakọbu ti oko dé, Lea jáde lọ pàdé rẹ̀, ó sọ fún un pé, “Ọ̀dọ̀ mi ni o gbọdọ̀ sùn ní alẹ́ òní, èso mandiraki ọmọ mi ni mo fi san owó ọ̀yà rẹ. Jakọbu bá sùn lọ́dọ̀ rẹ̀ di ọjọ́ keji.”

17. Ọlọrun gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Lea, ó lóyún, ó bí ọmọkunrin karun-un.

18. Lea ní “Ọlọrun san ẹ̀san fún mi, nítorí pé mo fún ọkọ mi ní iranṣẹbinrin mi.” Ó bá sọ ọmọ náà ní Isakari.

19. Lea tún lóyún, ó bí ọkunrin kẹfa.

20. Ó ní, “Ọlọrun ti fi ẹ̀bùn rere fún mi, nígbà yìí ni ọkọ mi yóo tó bu ọlá fún mi, nítorí pé mo bí ọkunrin mẹfa fún un,” nítorí náà ó sọ ọmọ náà ní Sebuluni.

21. Lẹ́yìn náà, ó bí obinrin kan, ó sọ ọ́ ní Dina.

22. Lẹ́yìn náà ni Ọlọrun ranti Rakẹli, ó gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, ó sì ṣí inú rẹ̀.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 30