Esau rí i pé Isaaki ti súre fún Jakọbu, ó sì ti rán an lọ sí Padani-aramu kí ó lọ fẹ́ iyawo, ati pé nígbà tí ó ń súre fún un, ó pàṣẹ fún un pé kò gbọdọ̀ fẹ́ ninu àwọn ọmọbinrin ará Kenaani.