Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 27:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Isaaki di arúgbó, tí ojú rẹ̀ sì di bàìbàì tóbẹ́ẹ̀ tí kò le ríran mọ́, ó pe Esau àkọ́bí rẹ̀, ó ní, “Ọmọ mi.” Esau sì dá a lóhùn pé, “Èmi nìyí.”

2. Isaaki wí pé, “Ṣé o rí i báyìí pé mo ti darúgbó, n kò sì mọ ọjọ́ ikú mi.

3. Kó àwọn ohun ọdẹ rẹ: ọrun ati ọfà rẹ, lọ sí ìgbẹ́, kí o sì pa ẹran wá fún mi.

4. Lẹ́yìn náà, se irú oúnjẹ aládùn tí mo fẹ́ràn fún mi, kí n jẹ ẹ́, kí ọkàn mi lè súre fún ọ kí n tó kú.”

5. Ní gbogbo ìgbà tí Isaaki ń bá Esau ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀, Rebeka ń gbọ́ gbogbo ohun tí wọ́n ń sọ. Nítorí náà nígbà tí Esau jáde lọ sinu ìgbẹ́,

6. Rebeka pe Jakọbu ọmọ rẹ̀, ó sọ fún un, ó ní, “Mo gbọ́ tí baba yín ń bá Esau ẹ̀gbọ́n rẹ sọ̀rọ̀,

7. pé kí ó lọ pa ẹran wá fún òun, kí ó sì se oúnjẹ aládùn kí òun lè jẹ ẹ́, kí òun sì súre fún un níwájú OLUWA kí òun tó kú.

8. Nítorí náà, ọmọ mi, fetí sílẹ̀ kí o sì ṣe ohun tí n óo sọ fún ọ.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 27