Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 26:27-30 BIBELI MIMỌ (BM)

27. Isaaki bá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ tún ń wá lọ́dọ̀ mi, nígbà tí ó jẹ́ pé ẹ kórìíra mi tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ lé mi kúrò lọ́dọ̀ yín?”

28. Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé OLUWA wà pẹlu rẹ, ni a bá rò pé, ó yẹ kí àdéhùn wà láàrin wa, kí á sì bá ọ dá majẹmu,

29. pé o kò ní pa wá lára, gẹ́gẹ́ bí àwa náà kò ti ṣe ọ́ níbi, àfi ire, tí a sì sìn ọ́ kúrò lọ́dọ̀ wa ní alaafia.”

30. Isaaki bá se àsè fún wọn, wọ́n jẹ, wọ́n mu.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 26