Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 26:13-26 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní àníkún títí ó fi di ọlọ́rọ̀.

14. Ó ní ọpọlọpọ agbo aguntan ati agbo mààlúù, pẹlu ọpọlọpọ iranṣẹ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Filistia bẹ̀rẹ̀ sí jowú rẹ̀.

15. Gbogbo kànga tí àwọn iranṣẹ Abrahamu baba rẹ̀ gbẹ́ ní àkókò tí Abrahamu wà láyé ni àwọn ará Filistia rọ́ yẹ̀ẹ̀pẹ̀ dí.

16. Abimeleki bá wí fún Isaaki pé, “Kúrò lọ́dọ̀ wa, nítorí pé o ti lágbára jù wá lọ.”

17. Isaaki kúrò níbẹ̀, ó lọ tẹ̀dó sí àfonífojì Gerari.

18. Isaaki tún àwọn kànga tí wọ́n ti gbẹ́ nígbà ayé Abrahamu baba rẹ̀ gbẹ́, nítorí pé, kò pẹ́ lẹ́yìn tí Abrahamu kú ni àwọn ará Filistia ti dí wọn. Ó sì sọ àwọn kànga náà ní orúkọ tí baba rẹ̀ sọ wọ́n.

19. Ṣugbọn nígbà tí àwọn iranṣẹ Isaaki gbẹ́ kànga kan ní àfonífojì náà tí wọ́n sì kan omi,

20. àwọn darandaran ará Gerari bá àwọn tí wọn ń da ẹran Isaaki jà, wọ́n wí pé, “Àwa ni a ni omi kànga yìí.” Nítorí náà ni Isaaki ṣe sọ kànga náà ní Eseki, nítorí pé wọ́n bá a jà nítorí rẹ̀.

21. Àwọn iranṣẹ Isaaki tún gbẹ́ kànga mìíràn, òun náà tún dìjà, nítorí náà Isaaki sọ ọ́ ní Sitina.

22. Ó kúrò níbẹ̀, ó lọ gbẹ́ kànga mìíràn, ẹnikẹ́ni kò sì bá a jà sí i, ó bá sọ ọ́ ní Rehoboti, ó wí pé, “Nisinsinyii Ọlọrun ti pèsè ààyè fún wa, a óo sì pọ̀ sí i ní ilẹ̀ yìí.”

23. Láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí Beeriṣeba.

24. OLUWA sì fara hàn án ní òru ọjọ́ tí ó rin ìrìn àjò náà, ó ní, “Èmi ni Ọlọrun Abrahamu, baba rẹ, má bẹ̀rù, nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo bukun ọ, n óo sì sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ nítorí ti Abrahamu iranṣẹ mi.”

25. Ó bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀, ó sì sin OLUWA. Níbẹ̀ ni ó pàgọ́ rẹ̀ sí, àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì gbẹ́ kànga kan sibẹ.

26. Abimeleki lọ sọ́dọ̀ Isaaki láti Gerari, òun ati Ahusati, olùdámọ̀ràn rẹ̀, ati Fikoli olórí ogun rẹ̀.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 26