Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 24:49-67 BIBELI MIMỌ (BM)

49. Nítorí náà, ẹ sọ fún mi bí ẹ óo bá ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu oluwa mi tabi ẹ kò ní ṣe ẹ̀tọ́, kí n lè mọ̀ bí n óo ṣe rìn.”

50. Labani ati Betueli dáhùn pé, “Ati ọ̀dọ̀ OLUWA ni nǹkan yìí ti wá, àwa kò sì ní sọ pé bẹ́ẹ̀ ni tabi bẹ́ẹ̀ kọ́.

51. Rebeka alára nìyí níwájú rẹ yìí, máa mú un lọ kí ó sì di aya ọmọ oluwa rẹ, bí OLUWA ti wí.”

52. Nígbà tí iranṣẹ Abrahamu gbọ́ ohun tí wọ́n sọ, ó wólẹ̀ ó sì dojúbolẹ̀ níwájú OLUWA.

53. Ó sì mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye tí a fi fadaka ati wúrà ṣe jáde, ati àwọn aṣọ àtàtà, ó kó wọn fún Rebeka. Ó sì kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye fún arakunrin rẹ̀ ati ìyá rẹ̀ pẹlu.

54. Nígbà náà ni òun ati àwọn tí wọ́n bá a wá tó jẹ, tí wọ́n sì mu, wọ́n sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà. Bí wọ́n ti jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, iranṣẹ Abrahamu wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n lọ jíṣẹ́ fún oluwa mi.”

55. Ẹ̀gbọ́n ati ìyá Rebeka dáhùn pé, “Jẹ́ kí omidan náà ṣe bí ọjọ́ mélòó kan sí i lọ́dọ̀ wa, bí kò tilẹ̀ ju ọjọ́ mẹ́wàá lọ, kí ó tó máa bá yín lọ!”

56. Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má wulẹ̀ dá mi dúró mọ́, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti ṣe ọ̀nà mi ní rere, ẹ jẹ́ kí n lọ bá oluwa mi.”

57. Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á kúkú pe omidan náà kí á bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”

58. Wọ́n bá pe Rebeka, wọ́n bi í pé, “Ṣé o óo máa bá ọkunrin yìí lọ?” Ó dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, n óo lọ.”

59. Wọ́n bá gbà pé kí Rebeka arabinrin wọn máa lọ, pẹlu olùtọ́jú rẹ̀ láti ìgbà èwe rẹ̀, ati iranṣẹ Abrahamu, pẹlu àwọn ọkunrin tí wọ́n bá a wá.

60. Wọ́n súre fún Rebeka, wọ́n wí pé, “Arabinrin wa, o óo bírún, o óo bígba. Àwọn ọmọ rẹ yóo máa borí àwọn ọ̀tá wọn.”

61. Rebeka ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ bá gun ràkúnmí, wọ́n tẹ̀lé ọkunrin náà. Bẹ́ẹ̀ ni iranṣẹ náà ṣe mú Rebeka lọ.

62. Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, Isaaki ti wá láti Beeri-lahai-roi, ó sì ń gbé ilẹ̀ Nẹgẹbu.

63. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, ó lọ ṣe àṣàrò ninu pápá, ojú tí ó gbé sókè, ó rí i tí àwọn ràkúnmí ń bọ̀.

64. Ojú tí Rebeka náà gbé sókè, ó rí Isaaki, ó sọ̀kalẹ̀ lórí ràkúnmí.

65. Ó bi iranṣẹ Abrahamu náà pé, “Ta ni ó ń rìn ninu pápá lọ́ọ̀ọ́kán tí ó ń bọ̀ wá pàdé wa yìí?” Iranṣẹ náà dá a lóhùn pé, “Olúwa mi ni.” Rebeka bá mú ìbòjú rẹ̀, ó dà á bojú.

66. Nígbà tí wọ́n pàdé Isaaki, iranṣẹ náà ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un.

67. Isaaki bá mú Rebeka wọ inú àgọ́ Sara ìyá rẹ̀, Rebeka sì di aya rẹ̀, Isaaki sì fẹ́ràn rẹ̀. Nígbà yìí ni Isaaki kò tó ṣọ̀fọ̀ ìyá rẹ̀ mọ́.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 24