Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 24:43-57 BIBELI MIMỌ (BM)

43. bí mo ti dúró nídìí kànga yìí, ọmọbinrin tí ó bá wá pọnmi, tí mo bá sì sọ fún pé, jọ̀wọ́, fún mi lómi mu ninu ìkòkò omi rẹ,

44. tí ó bá wí fún mi pé, “Omi nìyí, mu, n óo sì pọn fún àwọn ràkúnmí rẹ pẹlu”, nígbà náà ni n óo mọ̀ pé òun ni obinrin náà tí ìwọ OLUWA ti yàn láti jẹ́ aya ọmọ oluwa mi.’

45. Kí n tó dákẹ́ adura mi, Rebeka yọ pẹlu ìkòkò omi ní èjìká rẹ̀. Ó sọ̀kalẹ̀ lọ sinu odò, ó sì pọnmi. Mo bá wí fún un pé, ‘Jọ̀wọ́ fún mi lómi mu.’

46. Kíá ni ó sọ ìkòkò omi rẹ̀ kúrò ní èjìká, tí ó sì wí pé, ‘Omi nìyí, mu, n óo pọn fún àwọn ràkúnmí rẹ pẹlu.’ Mo bá mu omi, ó sì fún àwọn ràkúnmí mi lómi mu pẹlu.

47. Nígbà náà ni mo bi í ọmọ ẹni tí í ṣe. Ó dá mi lóhùn pé, Betueli ọmọ Nahori, tí Milika bí fún un ni baba òun. Nígbà tí mo gbọ́ bẹ́ẹ̀, mo fi òrùka sí imú rẹ̀, mo sì fi ẹ̀gbà ọwọ́ bọ̀ ọ́ lọ́wọ́.

48. Nígbà náà ni mo tẹríba, mo sì sin OLUWA, mo yin OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi lógo, ẹni tí ó tọ́ mi sí ọ̀nà tààrà láti wá fẹ́ ọmọ ẹbí oluwa mi fún ọmọ rẹ̀.

49. Nítorí náà, ẹ sọ fún mi bí ẹ óo bá ṣe ẹ̀tọ́ pẹlu oluwa mi tabi ẹ kò ní ṣe ẹ̀tọ́, kí n lè mọ̀ bí n óo ṣe rìn.”

50. Labani ati Betueli dáhùn pé, “Ati ọ̀dọ̀ OLUWA ni nǹkan yìí ti wá, àwa kò sì ní sọ pé bẹ́ẹ̀ ni tabi bẹ́ẹ̀ kọ́.

51. Rebeka alára nìyí níwájú rẹ yìí, máa mú un lọ kí ó sì di aya ọmọ oluwa rẹ, bí OLUWA ti wí.”

52. Nígbà tí iranṣẹ Abrahamu gbọ́ ohun tí wọ́n sọ, ó wólẹ̀ ó sì dojúbolẹ̀ níwájú OLUWA.

53. Ó sì mú àwọn ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye tí a fi fadaka ati wúrà ṣe jáde, ati àwọn aṣọ àtàtà, ó kó wọn fún Rebeka. Ó sì kó àwọn ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye fún arakunrin rẹ̀ ati ìyá rẹ̀ pẹlu.

54. Nígbà náà ni òun ati àwọn tí wọ́n bá a wá tó jẹ, tí wọ́n sì mu, wọ́n sùn níbẹ̀ ní alẹ́ ọjọ́ náà. Bí wọ́n ti jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji, iranṣẹ Abrahamu wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí n lọ jíṣẹ́ fún oluwa mi.”

55. Ẹ̀gbọ́n ati ìyá Rebeka dáhùn pé, “Jẹ́ kí omidan náà ṣe bí ọjọ́ mélòó kan sí i lọ́dọ̀ wa, bí kò tilẹ̀ ju ọjọ́ mẹ́wàá lọ, kí ó tó máa bá yín lọ!”

56. Ṣugbọn ó dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má wulẹ̀ dá mi dúró mọ́, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti ṣe ọ̀nà mi ní rere, ẹ jẹ́ kí n lọ bá oluwa mi.”

57. Wọ́n dáhùn pé, “Ẹ jẹ́ kí á kúkú pe omidan náà kí á bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 24