Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 24:4-18 BIBELI MIMỌ (BM)

4. ṣugbọn o óo lọ sí ìlú mi, lọ́dọ̀ àwọn ẹbí mi, láti fẹ́ aya fún Isaaki, ọmọ mi.”

5. Iranṣẹ náà dá a lóhùn pé, “Bí ọmọbinrin náà bá kọ̀ láti bá mi wá sí ilẹ̀ yìí, ṣé kí n mú ọmọ rẹ pada sí ilẹ̀ tí o ti wá síhìn-ín?”

6. Abrahamu dáhùn pé, “Rárá o! O kò gbọdọ̀ mú ọmọ mi pada sibẹ.

7. OLUWA Ọlọrun ọ̀run, tí ó mú mi jáde láti ilé baba mi, ati ilẹ̀ tí wọ́n bí mi sí, tí ó bá mi sọ̀rọ̀, tí ó sì búra fún mi pé, àwọn ọmọ mi ni òun yóo fi ilẹ̀ yìí fún, yóo rán angẹli rẹ̀ ṣáájú rẹ, o óo sì fẹ́ aya wá fún ọmọ mi láti ibẹ̀.

8. Ṣugbọn bí obinrin náà bá kọ̀ tí kò tẹ̀lé ọ, nígbà náà ọrùn rẹ yóo mọ́ ninu ìbúra tí o búra fún mi, ṣá má ti mú ọmọ mi pada sibẹ.”

9. Iranṣẹ náà bá ti ọwọ́ rẹ̀ bọ abẹ́ itan Abrahamu oluwa rẹ̀, ó sì búra láti ṣe ohun tí Abrahamu pa láṣẹ fún un.

10. Iranṣẹ náà mú mẹ́wàá ninu àwọn ràkúnmí oluwa rẹ̀, ó gba oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn àtàtà lọ́wọ́ oluwa rẹ̀, ó jáde lọ sí ilẹ̀ Mesopotamia, sí ìlú Nahori.

11. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ní déédé ìgbà tí àwọn obinrin máa ń jáde lọ pọn omi, ó mú kí àwọn ràkúnmí rẹ̀ kúnlẹ̀ lẹ́yìn odi ìlú lẹ́bàá kànga kan,

12. ó sì gbadura báyìí pé “Ìwọ OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, jọ̀wọ́, ṣe ọ̀nà mi ní rere lónìí, kí o sì fi ìfẹ́ ńlá rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí Abrahamu, oluwa mi.

13. Bí mo ti dúró lẹ́bàá kànga yìí, tí àwọn ọdọmọbinrin ìlú yìí sì ń jáde wá láti pọn omi,

14. jẹ́ kí ọmọbinrin tí mo bá sọ fún pé jọ̀wọ́ sọ ìkòkò omi rẹ kalẹ̀ kí o fún mi ní omi mu, tí ó sì dá mi lóhùn pé, ‘Omi nìyí, mu, n óo sì fún àwọn ràkúnmí rẹ mu pẹlu,’ jẹ́ kí olúwarẹ̀ jẹ́ ẹni náà tí o yàn fún Isaaki, iranṣẹ rẹ. Èyí ni n óo fi mọ̀ pé o ti fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn sí oluwa mi.”

15. Kí ó tó dákẹ́ adura rẹ̀ ni Rebeka ọmọ Betueli yọ sí i pẹlu ìkòkò omi ní èjìká rẹ̀. Ọmọ Nahori ni Betueli jẹ́, tí Milika bí fún un. Nahori yìí jẹ́ arakunrin Abrahamu.

16. Arẹwà wundia ni Rebeka, kò sì tíì mọ ọkunrin. Bí ó ti dé, ó sọ̀kalẹ̀ lọ sinu odò, ó pọn omi rẹ̀, ó sì jáde.

17. Iranṣẹ Abrahamu bá sáré tẹ̀lé e, ó bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ní omi díẹ̀ mu ninu ìkòkò rẹ.”

18. Ọmọbinrin náà dáhùn pé, “Omi nìyí, oluwa mi.” Ó sì yára gbé ìkòkò rẹ̀ lé ọwọ́ rẹ̀ láti fún un ní omi mu.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 24