Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 24:20-30 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Kíá, ó ti da omi tí ó kù ninu ìkòkò rẹ̀ sinu agbada tí ẹran fi ń mu omi, ó sáré pada lọ pọn sí i, títí tí gbogbo wọn fi mu omi káríkárí.

21. Ọkunrin náà fọwọ́ lẹ́rán, ó ń wò pé bóyá lóòótọ́ ni OLUWA ti ṣe ọ̀nà òun ní rere ni tabi bẹ́ẹ̀ kọ́.

22. Nígbà tí àwọn ràkúnmí rẹ̀ mu omi tán, tí gbogbo wọn yó, ọkunrin yìí fún un ní òrùka imú tí a fi wúrà ṣe, tí ó wọ̀n tó ìwọ̀n ìdajì ṣekeli, ati ẹ̀gbà ọwọ́ meji tí a fi wúrà ṣe tí ó wọ̀n tó ìwọ̀n ṣekeli wúrà mẹ́wàá.

23. Lẹ́yìn náà, ó bi í pé, “Jọ̀wọ́, kí ni orúkọ baba rẹ? Ǹjẹ́ ààyè ṣì wà ní ilé yín tí a lè wọ̀ sí ní alẹ́ yìí?”

24. Ó dá a lóhùn, ó ní, “Betueli, ọmọ tí Milika bí fún Nahori ni baba mi.”

25. Ó tún fi kún un pé, “A ní ọpọlọpọ koríko ati oúnjẹ ẹran, ààyè sì wà láti sùn ní ilé wa.”

26. Ọkunrin náà bá tẹríba, ó sì sin OLUWA,

27. ó sọ pé, “Ọpẹ́ ni fún ọ OLUWA Ọlọrun Abrahamu, oluwa mi, tí kò gbàgbé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ ati òdodo rẹ̀ sí oluwa mi. Ní tèmi, OLUWA ti tọ́ mi sọ́nà tààrà, sí ilé àwọn ìbátan oluwa mi.”

28. Ọmọbinrin náà bá sáré lọ sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún àwọn ará ilé ìyá rẹ̀.

29. Rebeka ní arakunrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Labani. Labani yìí ni ó sáré lọ bá ọkunrin náà ní ìdí kànga.

30. Lẹ́yìn tí ó rí òrùka ati ẹ̀gbà ọwọ́ lọ́wọ́ arabinrin rẹ̀, tí ó sì ti gbọ́ ohun tí Rebeka sọ pé ọkunrin náà sọ fún òun, ó lọ bá ọkunrin náà níbi tí ó dúró sí lẹ́bàá kànga pẹlu àwọn ràkúnmí rẹ̀.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 24