Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 23:16-20 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Abrahamu gbà bí Efuroni ti wí, ó bá wọn irinwo (400) ìwọ̀n ṣekeli fadaka tí Efuroni dárúkọ fún un lójú gbogbo wọn, ó lo ìwọ̀n tí àwọn oníṣòwò ìgbà náà ń lò.

17. Bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ Efuroni ní Makipela, tí ó wà ní apá ìhà ìlà oòrùn Mamure ṣe di ti Abrahamu, ati ihò tí ó wà ninu ilẹ̀ náà, ati gbogbo igi tí ó wà ninu rẹ̀ jákèjádò.

18. Gbogbo àwọn ará Hiti tí wọ́n wà níbẹ̀ jẹ́rìí sí i pé ilẹ̀ náà di ti Abrahamu.

19. Lẹ́yìn náà, Abrahamu lọ sin òkú Sara sinu ihò ilẹ̀ Makipela, tí ó wà ní ìhà ìlà oòrùn Mamure, ní agbègbè Heburoni ní ilẹ̀ Kenaani.

20. Ilẹ̀ náà ati ihò tí ó wà ninu rẹ̀ ni àwọn ará Hiti fi fún Abrahamu láti máa lò bí itẹ́ òkú.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 23