Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 22:15-24 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Angẹli OLUWA tún pe Abrahamu láti òkè ọ̀run ní ìgbà keji,

16. ó ní, “Mo fi ara mi búra pé nítorí ohun tí o ṣe yìí, tí o kò kọ̀ láti fún mi ní ọmọ rẹ kan ṣoṣo,

17. n óo bukun ọ lọpọlọpọ, n óo sọ àwọn ọmọ ọmọ rẹ di pupọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ati bíi yanrìn etí òkun. Àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóo máa ṣẹgun àwọn ọ̀tá wọn ní gbogbo ìgbà.

18. Nípasẹ̀ àwọn ọmọ rẹ ni n óo ti bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, nítorí pé o gbọ́ràn sí mi lẹ́nu.”

19. Abrahamu bá pada tọ àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ lọ, wọ́n bá jọ gbéra, wọ́n pada lọ sí Beeriṣeba, Abrahamu sì ń gbé ibẹ̀.

20. Lẹ́yìn náà, wọ́n wá sọ fún Abrahamu pé Milika ti bímọ fún Nahori arakunrin rẹ̀.

21. Usi ni àkọ́bí, Busi ni wọ́n bí tẹ̀lé e, lẹ́yìn náà Kemueli tíí ṣe baba Aramu.

22. Lẹ́yìn rẹ̀ ni wọ́n bí Kesedi, Haso, Pilidaṣi, Jidilafi ati Betueli.

23. Betueli ni baba Rebeka. Àwọn mẹjẹẹjọ yìí ni Milika bí fún Nahori, arakunrin Abrahamu.

24. Nahori tún ní obinrin mìíràn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Reuma, òun ni ó bí Teba, Gahamu, Tahaṣi, ati Mahaka fún Nahori.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 22