Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 21:24-32 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Abrahamu bá sọ pé òun yóo búra.

25. Abrahamu rò fún Abimeleki bí àwọn iranṣẹ Abimeleki ti fi ipá gba kànga omi kan lọ́wọ́ rẹ̀,

26. Abimeleki bá dá a lóhùn, ó ní “N kò mọ ẹni tí ó ṣe bẹ́ẹ̀, o kò sọ fún mi, n kò gbọ́ nǹkankan nípa rẹ̀, àfi bí o ti ń sọ yìí.”

27. Abrahamu fún Abimeleki ní aguntan ati mààlúù, àwọn mejeeji bá jọ dá majẹmu.

28. Abrahamu ya abo ọmọ aguntan meje ninu agbo rẹ̀ sọ́tọ̀.

29. Abimeleki bá bi Abrahamu, ó ní, “Kí ni ìtumọ̀ abo ọmọ aguntan meje tí o yà sọ́tọ̀ wọnyi?”

30. Abrahamu dá a lóhùn pé, “Gba abo ọmọ aguntan meje wọnyi lọ́wọ́ mi, kí o lè jẹ́ ẹlẹ́rìí mi pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.”

31. Ìdí rẹ̀ nìyí tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Beeriṣeba, nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn mejeeji ti búra.

32. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe dá majẹmu ní Beeriṣeba. Abimeleki ati Fikoli, olórí ogun rẹ̀, sì pada lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Filistia.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 21