Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 21:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA bẹ Sara wò gẹ́gẹ́ bí ó ti wí, ó sì ṣe fún un gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀.

2. Sara lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan fún Abrahamu lẹ́yìn tí ó ti di arúgbó, ní àkókò tí Ọlọrun sọ fún un.

3. Abrahamu sọ ọmọkunrin náà ní Isaaki.

4. Ó kọlà abẹ́ fún ọmọ náà nígbà tí ó di ọmọ ọjọ́ kẹjọ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pàṣẹ fún un.

5. Abrahamu jẹ́ ẹni ọgọrun-un (100) ọdún nígbà tí a bí Isaaki fún un.

6. Sara wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín, gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ ni yóo sì rẹ́rìn-ín.”

7. Ó tún wí pé, “Ta ni ó lè sọ fún Abrahamu pé Sara yóo fún ọmọ lọ́mú? Sibẹsibẹ mo bí ọmọ fún un nígbà tí ó ti di arúgbó.”

8. Ọmọ náà dàgbà, ó sì já lẹ́nu ọmú, Abrahamu sì se àsè ńlá ní ọjọ́ tí ọmọ náà já lẹ́nu ọmú.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 21