Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 19:16-29 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Ṣugbọn nígbà tí Lọti bẹ̀rẹ̀ sí lọ́ra, àwọn angẹli meji náà mú òun ati aya rẹ̀, pẹlu àwọn ọmọbinrin rẹ̀ mejeeji, wọ́n kó wọn jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú, nítorí pé OLUWA ṣàánú Lọti.

17. Nígbà tí wọ́n kó wọn jáde tán, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí yín; ẹ má ṣe wo ẹ̀yìn rárá, ẹ má sì ṣe dúró níbikíbi ní àfonífojì yìí, ẹ sá gun orí òkè lọ, kí ẹ má baà parun.”

18. Ṣugbọn Lọti wí fún wọn pé, “Áà! Rárá! oluwa mi.

19. Èmi iranṣẹ yín ti rí ojurere lọ́dọ̀ yín, ẹ sì ti ṣe mí lóore ńlá nípa gbígba ẹ̀mí mi là, ṣugbọn n kò ní le sálọ sí orí òkè, kí ijamba má baà ká mi mọ́ ojú ọ̀nà, kí n sì kú.

20. Ẹ wò ó, ìlú tí ó wà lọ́hùn-ún nì súnmọ́ tòsí tó láti sálọ, ó sì tún jẹ́ ìlú kékeré. Ẹ jẹ́ kí n sálọ sibẹ, ṣebí ìlú kékeré ni? Ẹ̀mí mi yóo sì là.”

21. OLUWA dáhùn pé, “Ó dára, mo gbọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ, n kò ní pa ìlú náà run.

22. Ṣe kíá, kí o sálọ sibẹ, nítorí n kò lè ṣe ohunkohun, títí tí o óo fi dé ibẹ̀.” Nítorí náà ni wọ́n ṣe sọ ìlú náà ní Soari.

23. Oòrùn ti yọ nígbà tí Lọti dé Soari.

24. OLUWA bá rọ òjò imí ọjọ́ ati iná láti ọ̀run wá sórí Sodomu ati Gomora,

25. ó sì pa ìlú náà run ati gbogbo àfonífojì náà. Ó pa gbogbo àwọn tí wọn ń gbé àwọn ìlú náà run, ati gbogbo ohun tí ó hù lórí ilẹ̀.

26. Ṣugbọn aya Lọti tí ó wà lẹ́yìn ọkọ rẹ̀ wo ẹ̀yìn, ó sì di ọ̀wọ̀n iyọ̀.

27. Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú Abrahamu lọ sí ibi tí ó ti dúró níwájú OLUWA,

28. ó wo ìhà ibi tí Sodomu ati Gomora wà, ati gbogbo àfonífojì náà, ó rí i pé gbogbo rẹ̀ ń yọ èéfín bí iná ìléru ńlá.

29. Ọlọrun ranti Abrahamu, nígbà tí ó pa àwọn ìlú tí ó wà ní àfonífojì náà, níbi tí Lọti ń gbé run, ó yọ Lọti jáde kúrò ninu ìparun.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 19