Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 17:1-15 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Abramu di ẹni ọdún mọkandinlọgọrun-un, OLUWA farahàn án, ó sọ fún un pé, “Èmi ni Ọlọrun Olodumare, máa gbọ́ tèmi, kí o sì jẹ́ pípé.

2. N óo bá ọ dá majẹmu kan, tí yóo wà láàrin èmi pẹlu rẹ, n óo sì bukun ọ lọpọlọpọ.”

3. Abramu bá dojúbolẹ̀, Ọlọrun tún wí fún un pé,

4. “Majẹmu tí mo bá ọ dá kò yẹ̀ rárá: O óo jẹ́ baba ńlá fún ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè.

5. Orúkọ rẹ kò ní jẹ́ Abramu mọ́, Abrahamu ni o óo máa jẹ́, nítorí mo ti sọ ọ́ di baba ńlá fún ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè.

6. N óo sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ, n óo sì sọ ọ́ di ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè, ọpọlọpọ ọba ni yóo sì ti ara rẹ jáde.”

7. “N óo fìdí majẹmu mi múlẹ̀ láàrin èmi pẹlu rẹ, ati atọmọdọmọ rẹ. Majẹmu náà yóo wà títí ayérayé pé, èmi ni n óo máa jẹ́ Ọlọrun rẹ ati ti atọmọdọmọ rẹ.

8. N óo fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ Kenaani, ilẹ̀ náà tí o ti jẹ́ àlejò yìí yóo di ìní rẹ títí ayérayé ati ti atọmọdọmọ rẹ, n óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn!”

9. Ọlọrun tún sọ fún Abrahamu pé, “Ìwọ pàápàá gbọdọ̀ pa majẹmu mi mọ́, ìwọ ati atọmọdọmọ rẹ láti ìrandíran wọn.

10. Majẹmu náà tí ó wà láàrin èmi pẹlu rẹ, ati atọmọdọmọ rẹ, tí ẹ gbọdọ̀ pamọ́ nìyí, gbogbo àwọn ọmọkunrin yín gbọdọ̀ kọlà abẹ́.

11. Ilà abẹ́ tí ẹ gbọdọ̀ kọ yìí ni yóo jẹ́ àmì majẹmu tí ó wà láàrin mi pẹlu yín.

12. Gbogbo ọmọkunrin tí ó bá ti pé ọmọ ọjọ́ mẹjọ láàrin yín gbọdọ̀ kọlà abẹ́, gbogbo ọmọkunrin ninu ìran yín, kì báà ṣe èyí tí a bí ninu ilé yín, tabi ẹrú tí ẹ rà lọ́wọ́ àjèjì, tí kì í ṣe ìran yín,

13. gbogbo ọmọ tí ẹ bí ninu ilé yín, ati ẹrú tí ẹ fi owó yín rà gbọdọ̀ kọlà abẹ́. Èyí yóo jẹ́ kí majẹmu mi wà lára yín, yóo sì jẹ́ majẹmu ayérayé.

14. Gbogbo ọkunrin tí kò bá kọlà abẹ́ ni a óo yọ kúrò láàrin àwọn eniyan rẹ̀, nítorí pé ó ti ba majẹmu mi jẹ́.”

15. Ọlọrun sọ fún Abrahamu pé, “Ní ti Sarai aya rẹ, má ṣe pè é ní Sarai mọ́, Sara ni orúkọ rẹ̀ yóo máa jẹ́.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 17