Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 15:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, OLUWA bá Abramu sọ̀rọ̀ lójú ìran, ó ní, “Má bẹ̀rù Abramu, n óo dáàbò bò ọ́, èrè rẹ yóo sì pọ̀ pupọ.”

2. Ṣugbọn Abramu dáhùn pé, “OLUWA Ọlọrun, kí ni o óo fún mi, n kò tíì bímọ títí di ìsinsìnyìí! Ṣé Elieseri ará Damasku yìí ni yóo jẹ́ àrólé mi ni?

3. O kò fún mi lọ́mọ, ẹrú tí wọ́n bí ninu ilé mi ni yóo di àrólé mi!”

4. OLUWA bá dá a lóhùn pé, “Kì í ṣe ọkunrin yìí ni yóo jẹ́ àrólé rẹ, ọmọ bíbí inú rẹ ni yóo jẹ́ àrólé rẹ.”

5. OLUWA bá mú un jáde, ó sì sọ fún un pé, “Wo ojú ọ̀run, kí o ka gbogbo ìràwọ̀ tí ó wà níbẹ̀ bí o bá lè kà wọ́n.” OLUWA bá sọ fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ rẹ yóo ṣe pọ̀ tó.”

6. Abramu gba OLUWA gbọ́, OLUWA sì kà á sí olódodo.

7. Ó sọ fún un pé “Èmi ni OLUWA tí ó mú ọ jáde láti ìlú Uri, ní ilẹ̀ Kalidea, láti fi ilẹ̀ yìí fún ọ ní ohun ìní.”

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 15