Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 14:5-13 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ní ọdún kẹrinla, Kedorilaomeri ati àwọn ọba tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀ wá, wọ́n ṣẹgun Refaimu tí ó wà ní Aṣiterotu Kanaimu. Bákan náà, wọ́n ṣẹgun àwọn Susimu tí wọ́n wà ní Hamu, àwọn Emimu tí wọ́n wà ní Ṣafe-kiriataimu,

6. ati àwọn ará Hori ní orí Òkè Seiri, títí dé Eliparani, lẹ́bàá aṣálẹ̀.

7. Nígbà náà ni wọ́n tó yipada tí wọ́n sì wá sí Enmiṣipati (tí ó tún ń jẹ́ Kadeṣi), wọ́n sì ṣẹgun gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Amaleki ati ti àwọn ará Amori tí ń gbé Hasasoni Tamari.

8. Nígbà náà ni ọba Sodomu, ati ọba Gomora jáde lọ, pẹlu ọba Adima, ọba Seboimu, ati ọba Bela, (tí ó tún ń jẹ́, Soari). Wọ́n pa ogun wọn pọ̀ ní àfonífojì Sidimu.

9. Wọ́n gbógun ti Kedorilaomeri, ọba Elamu, Tidali, ọba Goiimu, Amrafeli, ọba Babiloni ati Arioku, ọba Elasari. Ọba mẹrin dojú kọ ọba marun-un.

10. Àfonífojì Sidimu kún fún ihò tí wọ́n ti wa ọ̀dà ilẹ̀. Bí àwọn ọmọ ogun ọba Sodomu ati àwọn ọmọ ogun ọba Gomora ti ń sálọ, àwọn kan ninu wọn jìn sinu àwọn ihò náà, àwọn yòókù sá gun orí òkè lọ.

11. Àwọn ọ̀tá kó gbogbo ẹrù ati oúnjẹ àwọn ará Sodomu ati Gomora, wọ́n bá tiwọn lọ.

12. Ọwọ́ wọn tẹ Lọti, ọmọ arakunrin Abramu tí ń gbé ní Sodomu, wọ́n mú un lẹ́rú, wọ́n sì kó gbogbo ẹran ọ̀sìn ati gbogbo ohun ìní rẹ̀ lọ.

13. Nígbà náà ni ẹnìkan tí ó sá àsálà lójú ogun náà wá ròyìn fún Abramu, tí ó jẹ́ Heberu, tí ń gbé lẹ́bàá igi Oaku, ní igbó Mamure, ará Amori. Mamure ati àwọn arakunrin rẹ̀ Eṣikolu ati Aneri bá Abramu dá majẹmu.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 14