Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Jẹnẹsisi 10:11-25 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Láti ibẹ̀ ni ó ti lọ sí Asiria, ó sì tẹ Ninefe dó, ati Rehoboti Iri, ati Kala,

12. ati ìlú ńlá tí wọn ń pè ní Reseni tí ó wà láàrin Ninefe ati Kala.

13. Ijipti ni ó bí Ludimu, Anamimu, Lehabimu, Nafutuhimu,

14. Patirusimu, Kasiluhimu, (lọ́dọ̀ ẹni tí àwọn ará Filistia ti ṣẹ̀) ati Kafitorimu.

15. Àkọ́bí Kenaani ni Sidoni, òun náà ni ó bí Heti.

16. Kenaani yìí kan náà ni baba ńlá àwọn ará Jebusi, àwọn ará Amori, àwọn ará Girigaṣi,

17. àwọn ará Hifi, àwọn ará Ariki, àwọn ará Sini,

18. àwọn ará Arifadi, àwọn ará Semari, ati àwọn ará Hamati. Lẹ́yìn náà ni ìran àwọn ará Kenaani tàn káàkiri.

19. Ilẹ̀ àwọn ará Kenaani bẹ̀rẹ̀ láti Sidoni, ní ìhà Gerari, ó lọ títí dé Gasa, ati sí ìhà Sodomu, Gomora, Adima, ati Seboimu títí dé Laṣa.

20. Àwọn ọmọ Hamu nìwọ̀nyí ní ìdílé ìdílé wọn, olukuluku ní agbègbè tirẹ̀, oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè ni wọ́n, wọ́n sì ń sọ oríṣìíríṣìí èdè.

21. Ṣemu, ẹ̀gbọ́n Jafẹti, náà bí àwọn ọmọ tirẹ̀, òun ni baba ńlá gbogbo àwọn ọmọ Eberi.

22. Òun náà ni ó bí Elamu, Aṣuri, Apakiṣadi, Ludi, ati Aramu.

23. Àwọn ọmọ Aramu ni: Usi, Huli, Geteri, ati Maṣi.

24. Apakiṣadi ni baba Ṣela, Ṣela sì ni baba Eberi.

25. Àwọn ọmọkunrin meji ni Eberi bí, orúkọ ekinni ni Pelegi, nítorí pé ní ìgbà tirẹ̀ ni ayé pínyà, orúkọ ekeji ni Jokitani.

Ka pipe ipin Jẹnẹsisi 10