Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 9:10-18 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n,ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ sì ni làákàyè.

11. Nípasẹ̀ mi ẹ̀mí rẹ yóo gùn.Ọpọlọpọ ọdún ni o óo sì lò lórí ilẹ̀ alààyè.

12. Bí o bá gbọ́n, o óo jèrè ọgbọ́n rẹ,Bí o bá sì jẹ́ pẹ̀gànpẹ̀gàn, ìwọ nìkan ni o óo jèrè rẹ̀.

13. Aláriwo ni obinrin tí kò gbọ́n,oníwọ̀ra ni, kò sì ní ìtìjú.

14. Á máa jókòó lẹ́nu ọ̀nà ilé rẹ̀,á jókòó ní ibi tí ó ga láàrin ìlú.

15. A máa kígbe pe àwọn tí ń kọjá lọ,àwọn tí ń bá tiwọn lọ jẹ́ẹ́jẹ́ wọn, pé,

16. “Ẹni tí ó bá jẹ́ aláìmọ̀kan, kí ó máa bọ̀!”Ó sì wí fún àwọn òmùgọ̀ pé,

17. “Omi tí eniyan bá jí mu a máa dùn,oúnjẹ tí a bá jí jẹ, oyinmọmọ ni.”

18. Àwọn tí wọ́n bá yà sọ́dọ̀ rẹ̀ kò ní mọ̀ pé ikú wà ní ilé rẹ̀,ati pé inú isà òkú ni àwọn tí wọ́n bá wọ ilé rẹ̀ wọ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 9