Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 9:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọgbọ́n ti kọ́lé,ó ti gbé àwọn òpó rẹ̀ mejeeje nàró.

2. Ó ti pa ẹran rẹ̀,ó ti pọn ọtí waini rẹ̀,ó sì ti tẹ́ tabili rẹ̀ kalẹ̀.

3. Ó ti rán àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀kí wọn lọ máa kígbe lórí àwọn òkè láàrin ìlú pé:

4. “Ẹ yà síbí ẹ̀yin òpè!”Ó sọ fún ẹni tí kò lọ́gbọ́n pé,

5. “Máa bọ̀, wá jẹ lára oúnjẹ mi,kí o sì mu ninu ọtí waini tí mo ti pò.

6. Fi àìmọ̀kan sílẹ̀, kí o sì yè,kí o máa rin ọ̀nà làákàyè.”

7. Ẹni tí ń tọ́ oníyẹ̀yẹ́ eniyan sọ́nà fẹ́ kan àbùkù,ẹni tí ń bá ìkà eniyan wí ń wá ìfarapa fún ara rẹ̀.

8. Má ṣe bá oníyẹ̀yẹ́ eniyan wí,kí ó má baà kórìíra rẹ,bá ọlọ́gbọ́n wí, yóo sì fẹ́ràn rẹ.

9. Kọ́ ọlọ́gbọ́n, yóo tún gbọ́n sí i,kọ́ olódodo, yóo sì tún ní ìmọ̀ kún ìmọ̀.

10. Ìbẹ̀rù OLUWA ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n,ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ sì ni làákàyè.

11. Nípasẹ̀ mi ẹ̀mí rẹ yóo gùn.Ọpọlọpọ ọdún ni o óo sì lò lórí ilẹ̀ alààyè.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 9