Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 8:6-18 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ pataki ni mo fẹ́ sọ.Ohun tí ó tọ́ ni n óo sì fi ẹnu mi sọ.

7. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ ni yóo ti ẹnu mi jáde,nítorí mo kórìíra ọ̀rọ̀ burúkú.

8. Òdodo ni gbogbo ọ̀rọ̀ ẹnu mi,kò sí ìtànjẹ tabi ọ̀rọ̀ àrékérekè ninu wọn.

9. Gbogbo ọ̀rọ̀ náà tọ́ lójú ẹni tí ó mòye,wọn kò sì ní àbùkù lọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ní ìmọ̀.

10. Gba ẹ̀kọ́ mi dípò fadaka,ati ìmọ̀ dípò ojúlówó wúrà,

11. nítorí ọgbọ́n níye lórí ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ,kò sí ohun tí o fẹ́, tí a lè fi wé e.

12. Èmi, ọgbọ́n, òye ni mò ń bá gbélé,mo ṣe àwárí ìmọ̀ ati làákàyè.

13. Ẹni tó bá bẹ̀rù OLUWA, yóo kórìíra ibi,mo kórìíra ìwà ìgbéraga, ọ̀nà ibi ati ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́.

14. Èmi ni mo ní ìmọ̀ràn ati ọgbọ́n tí ó yè kooro,mo sì ní òye ati agbára.

15. Nípasẹ̀ mi ni àwọn ọba fi ń ṣe ìjọba,tí àwọn alákòóso sì ń pàṣẹ òdodo.

16. Nípasẹ̀ mi ni àwọn olórí ń ṣe àkóso,gbogbo àwọn ọlọ́lá sì ń ṣe àkóso ayé.

17. Mo fẹ́ràn gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi,àwọn tí wọ́n bá fi tọkàntọkàn wá mi yóo sì rí mi.

18. Ọrọ̀ ati iyì wà níkàáwọ́ mi,ọrọ̀ tíí tọ́jọ́, ati ibukun.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 8