Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 8:30-36 BIBELI MIMỌ (BM)

30. èmi ni oníṣẹ́ ọnà tí mo wà lọ́dọ̀ rẹ̀,Inú mi a máa dùn lojoojumọ,èmi a sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀ nígbà gbogbo.

31. Mo láyọ̀ ninu ayé tí àwọn ẹ̀dá alààyè ń gbé,inú mi sì ń dùn sí àwọn ọmọ eniyan.

32. “Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi,ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà mi.

33. Ẹ gbọ́ ìtọ́ni, kí ẹ sì kọ́gbọ́n,ẹ má sì ṣe àìnáání rẹ̀.

34. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbọ́ tèmi,tí ó ń ṣọ́nà lojoojumọ ní ẹnu ọ̀nà àgbàlá mi,tí ó dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé mi.

35. Ẹni tí ó rí mi, rí ìyè,ó sì rí ojurere lọ́dọ̀ OLUWA,

36. ṣugbọn ẹni tí kò bá rí mi, ó pa ara rẹ̀ lára,gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi, ikú ni wọ́n fẹ́ràn.”

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 8