Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 8:20-34 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ọ̀nà òdodo ni èmi ń rìn,ojú ọ̀nà tí ó tọ́ ni mò ń tọ̀.

21. Èmi a máa fún àwọn tí wọ́n fẹ́ mi ní ọrọ̀,n óo máa mú kí ìṣúra wọn kún.

22. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ayé ni OLUWA ti dá mi,kí ó tó bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀.

23. Láti ayébáyé ni a ti yàn mí,láti ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé rárá.

24. Kí ibú omi tó wà ni mo ti wà,nígbà tí kò tíì sí àwọn orísun omi.

25. Kí á tó dá àwọn òkè ńlá sí ààyè wọn,kí àwọn òkè kéékèèké tó wà, ni mo ti wà.

26. Kí Ọlọrun tó dá ayé, ati pápá oko,kí ó tó dá erùpẹ̀ ilẹ̀.

27. Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó dá ojú ọ̀run sí ààyè rẹ̀,tí ó ṣe àmì bìrìkìtì sórí ibú,ní ibi tí ó dàbí ẹni pé ilẹ̀ ati ọ̀run ti pàdé,

28. nígbà tí ó ṣe awọsanma lọ́jọ̀,tí ó fi ìpìlẹ̀ orísun omi sọ ilẹ̀,

29. nígbà tí ó pààlà sí ibi tí òkun gbọdọ̀ kọjá,kí omi má baà kọjá ààyè rẹ̀.Nígbà tí ó sàmì sí ibi tí ìpìlẹ̀ ayé wà,

30. èmi ni oníṣẹ́ ọnà tí mo wà lọ́dọ̀ rẹ̀,Inú mi a máa dùn lojoojumọ,èmi a sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀ nígbà gbogbo.

31. Mo láyọ̀ ninu ayé tí àwọn ẹ̀dá alààyè ń gbé,inú mi sì ń dùn sí àwọn ọmọ eniyan.

32. “Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi,ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà mi.

33. Ẹ gbọ́ ìtọ́ni, kí ẹ sì kọ́gbọ́n,ẹ má sì ṣe àìnáání rẹ̀.

34. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbọ́ tèmi,tí ó ń ṣọ́nà lojoojumọ ní ẹnu ọ̀nà àgbàlá mi,tí ó dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé mi.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 8