Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 8:16-30 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Nípasẹ̀ mi ni àwọn olórí ń ṣe àkóso,gbogbo àwọn ọlọ́lá sì ń ṣe àkóso ayé.

17. Mo fẹ́ràn gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn mi,àwọn tí wọ́n bá fi tọkàntọkàn wá mi yóo sì rí mi.

18. Ọrọ̀ ati iyì wà níkàáwọ́ mi,ọrọ̀ tíí tọ́jọ́, ati ibukun.

19. Èso mi dára ju wúrà dáradára lọ,àyọrísí mi sì dára ju ojúlówó fadaka lọ.

20. Ọ̀nà òdodo ni èmi ń rìn,ojú ọ̀nà tí ó tọ́ ni mò ń tọ̀.

21. Èmi a máa fún àwọn tí wọ́n fẹ́ mi ní ọrọ̀,n óo máa mú kí ìṣúra wọn kún.

22. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀dá ayé ni OLUWA ti dá mi,kí ó tó bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀.

23. Láti ayébáyé ni a ti yàn mí,láti ìbẹ̀rẹ̀, kí á tó dá ayé rárá.

24. Kí ibú omi tó wà ni mo ti wà,nígbà tí kò tíì sí àwọn orísun omi.

25. Kí á tó dá àwọn òkè ńlá sí ààyè wọn,kí àwọn òkè kéékèèké tó wà, ni mo ti wà.

26. Kí Ọlọrun tó dá ayé, ati pápá oko,kí ó tó dá erùpẹ̀ ilẹ̀.

27. Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó dá ojú ọ̀run sí ààyè rẹ̀,tí ó ṣe àmì bìrìkìtì sórí ibú,ní ibi tí ó dàbí ẹni pé ilẹ̀ ati ọ̀run ti pàdé,

28. nígbà tí ó ṣe awọsanma lọ́jọ̀,tí ó fi ìpìlẹ̀ orísun omi sọ ilẹ̀,

29. nígbà tí ó pààlà sí ibi tí òkun gbọdọ̀ kọjá,kí omi má baà kọjá ààyè rẹ̀.Nígbà tí ó sàmì sí ibi tí ìpìlẹ̀ ayé wà,

30. èmi ni oníṣẹ́ ọnà tí mo wà lọ́dọ̀ rẹ̀,Inú mi a máa dùn lojoojumọ,èmi a sì máa yọ̀ níwájú rẹ̀ nígbà gbogbo.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 8