Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 8:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọgbọ́n ń pe eniyan,òye ń pariwo.

2. Ó dúró ní ibi tí ó ga lẹ́bàá ọ̀nà,ati ní ojú ọ̀nà tóóró,

3. ó ń kígbe lóhùn rara lẹ́nu ibodè àtiwọ ìlú,ó ń ké ní ẹnu ọ̀nà àbáwọlé pẹlu,ó ń wí pé:

4. “Ẹ̀yin eniyan ni mò ń pè,gbogbo ọmọ eniyan ni mò ń ké sí.

5. Ẹ̀yin òpè, ẹ kọ́ ọgbọ́n,ẹ̀yin òmùgọ̀, ẹ fetí sí òye.

6. Ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́, nítorí pé ọ̀rọ̀ pataki ni mo fẹ́ sọ.Ohun tí ó tọ́ ni n óo sì fi ẹnu mi sọ.

7. Ọ̀rọ̀ òtítọ́ ni yóo ti ẹnu mi jáde,nítorí mo kórìíra ọ̀rọ̀ burúkú.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 8