Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 7:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọmọ mi, pa ọ̀rọ̀ mi mọ́,kí o sì fi òfin mi sinu ọkàn rẹ.

2. Pa òfin mi mọ́, kí o lè yè,pa ẹ̀kọ́ mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹyin ojú rẹ,

3. wé wọn mọ́ ìka rẹ,kí o sì kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ.

4. Sọ fún ọgbọ́n pé, “Ìwọ ni arabinrin mi,”kí o sì pe ìmọ̀ ní ọ̀rẹ́ kòríkòsùn rẹ,

5. kí wọ́n baà lè pa ọ́ mọ́,kúrò lọ́dọ̀ alágbèrè obinrin,ati kúrò lọ́wọ́ onírìnkurìn pẹlu ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀.

6. Mo yọjú wo ìta,láti ojú fèrèsé ilé mi.

7. Mo rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní ìrírí,mo ṣe akiyesi pé láàrin wọn,ọmọkunrin kan wà tí kò gbọ́n.

8. Ó ń lọ ní òpópónà, lẹ́bàá kọ̀rọ̀ ilé alágbèrè obinrin náà,

9. ní àṣáálẹ́, nígbà tí ọjọ́ ń pofírí,tí ilẹ̀ ti ń ṣú, tí òkùnkùn ti ń kùn.

10. Obinrin kan lọ pàdé rẹ̀,ó wọ aṣọ aṣẹ́wó,ọkàn rẹ̀ kún fún ẹ̀tàn.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 7