Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 6:20-29 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ọmọ mi, pa òfin baba rẹ mọ́,má sì ṣe kọ ẹ̀kọ́ ìyá rẹ sílẹ̀.

21. Fi wọ́n sọ́kàn nígbà gbogbo,kí o sì so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ.

22. Nígbà tí o bá ń lọ, wọn yóo máa tọ́ ọ,bí o bá sùn, wọn yóo máa ṣọ́ ọ,bí o bá jí, wọn yóo máa bá ọ sọ̀rọ̀.

23. Nítorí fìtílà ni òfin,ìmọ́lẹ̀ ni ẹ̀kọ́, ìbáwí sì jẹ́ ọ̀nà ìyè,

24. láti pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ obinrin burúkú,ati lọ́wọ́ ẹnu alágbèrè obinrin tí ó dùn lọ́rọ̀.

25. Má jẹ́ kí ẹwà rẹ̀ wù ọ́,má sì ṣe jẹ́ kí ó fi ìpéǹpéjú rẹ̀ mú ọ.

26. Owó tí aṣẹ́wó yóo gbà kò ju owó burẹdi lọ,ṣugbọn gbogbo ẹ̀mí rẹ ni alágbèrè yóo fi ọgbọ́n gbà.

27. Ǹjẹ́ ẹnìkan lè gbé iná ka àyà,kí aṣọ rẹ̀ má jó?

28. Tabi eniyan lè rìn lórí ẹ̀yinná,kí iná má jó o lẹ́sẹ̀?

29. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹni tí ó lọ bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀ rí,kò sí ẹni tí yóo ṣe bẹ́ẹ̀ tí yóo lọ láìjìyà.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 6