Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 6:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọmọ mi, bí o bá ṣe onídùúró fún aládùúgbò rẹ,tí o jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún àjèjì,

2. tí o bá bọ́ sinu tàkútétí o fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ dẹ fún ara rẹ,tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ sì ti kó bá ọ,

3. o ti bọ́ sọ́wọ́ aládùúgbò rẹ.Nítorí náà báyìí ni kí o ṣe, ọmọ mi,kí o lè gba ara rẹ là:lọ bá a kíákíá, kí o sì bẹ̀ ẹ́.

4. Má sùn,má sì tòògbé,

5. gba ara rẹ sílẹ̀ bí àgbọ̀nrín tíí gba ara rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ọdẹ,àní, bí ẹyẹ tíí ṣe, tíí fi í bọ́ lọ́wọ́ pẹyẹpẹyẹ.

6. Ìwọ ọ̀lẹ, tọ èèrùn lọ,ṣàkíyèsí ìṣe rẹ̀, kí o sì kọ́gbọ́n.

7. Ẹ̀dá tí kò ní olórí, tabi alabojuto, tabi aláṣẹ

8. sibẹsibẹ, a máa tọ́jú oúnjẹ rẹ̀ ní àkókò ẹ̀ẹ̀rùn;a sì máa kó oúnjẹ jọ, ní àkókò ìkórè.

9. O óo ti sùn pẹ́ tó, ìwọ ọ̀lẹ?Ìgbà wo ni o óo tají lójú oorun?

10. Oorun díẹ̀, òògbé díẹ̀,ìkáwọ́gbera díẹ̀ láti sinmi,

11. yóo jẹ́ kí òṣì dé bá ọ, bí ọlọ́ṣà dé bá eniyan. Àìní yóo sì dé bá ọ bíi jagunjagun dé báni.

12. Eniyan lásán, ìkà eniyan, a máa rìn káàkiri,a máa sọ̀rọ̀ àrékérekè,

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 6