Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 5:6-13 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ó kọ̀ láti rin ọ̀nà ìyè,ọ̀nà rẹ̀ wọ́, kò sì mọ̀.

7. Nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi,ẹ má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu.

8. Ẹ jìnnà sí alágbèrè obinrin,kí ẹ má tilẹ̀ súnmọ́ ẹnu ọ̀nà rẹ̀,

9. kí ẹ má baà gbé ògo yín fún ẹlòmíràn,kí ẹ sì fi ìgbé ayé yín lé aláìláàánú lọ́wọ́.

10. Kí àjèjì má baà jèrè iṣẹ́ yín,kí làálàá rẹ má sì bọ́ sápò àlejò.

11. Kí o má baà kérora nígbẹ̀yìn ayé rẹ,nígbà tí o bá di ìjẹ fún ẹni ẹlẹ́ni

12. nígbà náà ni o óo wí pé,“Kí ló dé tí mo kórìíra ìtọ́ni,tí ọkàn mi sì kẹ́gàn ìbáwí!

13. N kò fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn olùkọ́ min kò sì gba ti àwọn tí wọn ń tọ́ mi sọ́nà.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 5