Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 5:17-23 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Tìrẹ nìkan ṣoṣo ni kí ó jẹ́,má jẹ́ kí àjèjì bá ọ pín ninu rẹ̀.

18. Jẹ́ kí orísun rẹ ní ibukun,kí inú rẹ sì máa dùn sí iyawo tí o fi àárọ̀ gbé.

19. Olólùfẹ́ rẹ tí ó dára bí abo egbin.Jẹ́ kí ẹwù rẹ̀ máa mú inú rẹ dùn nígbà gbogbo,kí ìfẹ́ rẹ̀ máa mú orí rẹ yá nígbàkúùgbà.

20. Kí ló dé, ọmọ mi,tí ìfẹ́ alágbèrè obinrin yóo fi wọ̀ ọ́ lọ́kàn,tí o óo fi máa dìrọ̀ mọ́ obinrin olobinrin?

21. Nítorí OLUWA rí gbogbo ohun tí eniyan ń ṣe,ó sì ń ṣàkíyèsí gbogbo ìrìn rẹ̀.

22. Eniyan burúkú a máa jìn sinu ọ̀fìn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,a sì bọ́ sinu ìyọnu nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

23. Yóo kú nítorí àìgba ìtọ́ni,yóo sì sọnù nítorí ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 5