Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 4:5-19 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Jẹ́ ọlọ́gbọ́n kí o sì ní ìmọ̀.Má gbàgbé, má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu.

6. Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóo pa ọ́ mọ́,fẹ́ràn rẹ̀, yóo sì dáàbò bò ọ́.

7. Bí o bá fẹ́ gbọ́n, bẹ̀rẹ̀ sí kọ́gbọ́n,ohun yòówù tí o lè tún ní,ọgbọ́n ló jù, nítorí náà jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

8. Gbé ọgbọ́n lárugẹ, yóo sì gbé ọ ga,yóo bu ọlá fún ọ, bí o bá gbà á mọ́ra.

9. Yóo fi nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó lẹ́wà bò ọ́ lórí,yóo sì dé ọ ní adé dáradára.”

10. Gbọ́, ọmọ mi, gba ẹ̀kọ́ mi,kí ẹ̀mí rẹ lè gùn.

11. Mo ti kọ́ ọ ní ọgbọ́n,mo sì ti fẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà òtítọ́.

12. Nígbà tí o bá ń rìn, o kò ní rí ìdínà,nígbà tí o bá ń sáré, o kò ní fi ẹsẹ̀ kọ.

13. Di ẹ̀kọ́ mú ṣinṣin,má jẹ́ kí ó bọ́,pa á mọ́, nítorí òun ni ìyè rẹ.

14. Má ṣe gba ọ̀nà ẹni ibi,má sì ṣe rin ọ̀nà eniyan burúkú.

15. Yẹra fún un,má tilẹ̀ kọjú sí ọ̀nà ibẹ̀,ṣugbọn gba ibòmíràn, kí o máa bá tìrẹ lọ.

16. Nítorí wọn kì í lè é sùn, bí wọn kò bá tíì ṣe ibi,oorun kì í kùn wọ́n, tí wọn kò bá tíì fa ìṣubú eniyan.

17. Ìkà ṣíṣe ni oúnjẹ wọn,ìwà ipá sì ni ọtí waini wọn.

18. Ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí ìmọ́lẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́,tí ń mọ́lẹ̀ sí i láti ìdájí títí tí ilẹ̀ yóo fi mọ́ kedere.

19. Ọ̀nà eniyan burúkú dàbí òkùnkùn biribiri,wọn kò mọ ohun tí wọn yóo dìgbò lù.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 4