Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 4:13-27 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Di ẹ̀kọ́ mú ṣinṣin,má jẹ́ kí ó bọ́,pa á mọ́, nítorí òun ni ìyè rẹ.

14. Má ṣe gba ọ̀nà ẹni ibi,má sì ṣe rin ọ̀nà eniyan burúkú.

15. Yẹra fún un,má tilẹ̀ kọjú sí ọ̀nà ibẹ̀,ṣugbọn gba ibòmíràn, kí o máa bá tìrẹ lọ.

16. Nítorí wọn kì í lè é sùn, bí wọn kò bá tíì ṣe ibi,oorun kì í kùn wọ́n, tí wọn kò bá tíì fa ìṣubú eniyan.

17. Ìkà ṣíṣe ni oúnjẹ wọn,ìwà ipá sì ni ọtí waini wọn.

18. Ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí ìmọ́lẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́,tí ń mọ́lẹ̀ sí i láti ìdájí títí tí ilẹ̀ yóo fi mọ́ kedere.

19. Ọ̀nà eniyan burúkú dàbí òkùnkùn biribiri,wọn kò mọ ohun tí wọn yóo dìgbò lù.

20. Ọmọ mi, fetí sí ọ̀rọ̀ mi,tẹ́tí sílẹ̀ sí ohun tí mò ń sọ.

21. Má jẹ́ kí wọn rú ọ lójú,fi wọ́n sọ́kàn.

22. Nítorí pé ìyè ni wọ́n jẹ́ fún àwọn tí ó rí wọn,ati ìwòsàn fún gbogbo ẹran ara wọn.

23. Ṣọ́ra pẹlu èrò ọkàn rẹ,nítorí èrò ọkàn ni orísun ìyè.

24. Má lọ́wọ́ ninu ọ̀rọ̀ ìsọkúsọ,sì jìnnà sí ọ̀rọ̀ àgàbàgebè.

25. Jẹ́ kí ojú rẹ máa wo ọ̀kánkán,kí o sì kọjú sí ibi tí ò ń lọ tààrà.

26. Kíyèsí ìrìn ẹsẹ̀ rẹ,gbogbo ọ̀nà rẹ yóo sì là.

27. Má ṣe yà sí ọ̀tún tabi sí òsì,yipada kúrò ninu ibi.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 4