Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 4:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀yin ọmọ, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ baba yín,ẹ tẹ́tí sílẹ̀, kí ẹ lè ní ìmọ̀,

2. nítorí pé mo fun yín ní ìlànà rere,ẹ má ṣe kọ ẹ̀kọ́ mi.

3. Nígbà tí mo wà ní ọmọde lọ́dọ̀ baba mi,tí mo jẹ́ ẹni ìkẹ́, ọ̀kan ṣoṣo lọ́wọ́ ìyá mi,

4. baba mi kọ́ mi, ó ní,“Fi ọ̀rọ̀ mi sọ́kàn,pa òfin mi mọ́, kí o lè wà láàyè.

5. Jẹ́ ọlọ́gbọ́n kí o sì ní ìmọ̀.Má gbàgbé, má sì kọ ọ̀rọ̀ sí mi lẹ́nu.

6. Má ṣe kọ ọgbọ́n sílẹ̀, yóo pa ọ́ mọ́,fẹ́ràn rẹ̀, yóo sì dáàbò bò ọ́.

7. Bí o bá fẹ́ gbọ́n, bẹ̀rẹ̀ sí kọ́gbọ́n,ohun yòówù tí o lè tún ní,ọgbọ́n ló jù, nítorí náà jẹ́ ọlọ́gbọ́n.

8. Gbé ọgbọ́n lárugẹ, yóo sì gbé ọ ga,yóo bu ọlá fún ọ, bí o bá gbà á mọ́ra.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 4