Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 30:4-15 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ta ló ti lọ sí ọ̀run rí, tí ó sì tún pada wá?Ta ló ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ọwọ́ rẹ̀?Ta ló ti fi aṣọ rẹ̀ di omi?Ta ló fi ìdí gbogbo òpin ayé múlẹ̀?Kí ni orúkọ olúwarẹ̀? Kí sì ni orúkọ ọmọ rẹ̀?Ṣé o mọ̀ ọ́n!

5. Kò sí ọ̀rọ̀ Ọlọrun kankan tí ó ń yẹ̀,òun ni ààbò fún àwọn tí wọ́n wá ààbò lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

6. Má fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀,kí ó má baà bá ọ wí,kí o má baà di òpùrọ́.”

7. Nǹkan meji ni mò ń tọrọ lọ́wọ́ rẹ,má ṣe fi wọ́n dù mí kí n tó kú.

8. Jẹ́ kí ìwà èké ati irọ́ pípa jìnnà sí mi,má jẹ́ kí n talaka, má sì jẹ́ kí n di ọlọ́rọ̀,fún mi ní ìwọ̀nba oúnjẹ tí ó tó mi jẹ,

9. kí n má baà yó tán, kí n sẹ́ ọ,kí n wí pé, “Ta ni ń jẹ́ OLUWA?”Má sì jẹ́ kí n tòṣì, kí n má baà jalè,kí n sì kó ẹ̀gbin bá orúkọ Ọlọrun.

10. Má ba iranṣẹ jẹ́ lójú ọ̀gá rẹ̀,kí ó má baà gbé ọ ṣépè, kí o sì di ẹlẹ́bi.

11. Àwọn kan wà tí wọn ń gbé baba wọn ṣépè,tí wọn kò sì súre fún ìyá wọn.

12. Àwọn tí wọ́n mọ́ lójú ara wọn,ṣugbọn a kò tíì wẹ èérí wọn nù.

13. Àwọn kan wà tí ojú wọ́n ga,lókè lókè ni ojú wọn wà.

14. Àwọn kan wà tí eyín wọn dàbí idà,kìkì ọ̀bẹ ló kún èrìgì wọn,láti jẹ àwọn talaka run lórí ilẹ̀ ayé,ati láti pa àwọn aláìní run láàrin àwọn eniyan.

15. Eṣúṣú bí ọmọbinrin meji, ó sì sọ àwọn mejeeji ni:“Mú wá, Mú wá.”Àwọn nǹkan pupọ wà tí kì í ní ìtẹ́lọ́rùn,wọ́n pọ̀ tí nǹkan kìí tó:

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 30