Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 30:24-33 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Àwọn nǹkan mẹrin kan wà tí wọ́n kéré ninu ayé,sibẹsibẹ wọ́n gbọ́n lọpọlọpọ:

25. àwọn èèrà kò lágbára,ṣugbọn wọn a máa kó oúnjẹ wọn jọ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.

26. Àwọn ehoro ìgbẹ́ kò lágbára,sibẹsibẹ wọ́n ń kọ́ ilé sí pàlàpálá òkúta.

27. Àwọn eṣú kò ní ọba,sibẹsibẹ wọ́n ń rìn ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.

28. Eniyan lè fi ọwọ́ mú aláǹgbá,sibẹsibẹ wọ́n pọ̀ ní ààfin ọba.

29. Àwọn nǹkan mélòó kan wà tí ìrìn yẹ,àwọn nǹkan pọ̀ tí ìrìn ẹsẹ̀ wọn máa ń wu eniyan:

30. Kinniun, alágbára jùlọ láàrin àwọn ẹranko,kì í sì í sá fún ẹnikẹ́ni.

31. Àkùkọ gàgàrà ati ẹran òbúkọ,ati ọba tí ń yan níwájú àwọn eniyan rẹ̀.

32. Bí o bá ti ń hùwà òmùgọ̀, tí ò ń gbé ara rẹ ga,tabi tí o tí ń gbèrò ibi,fi òpin sí i, kí o sì ronú.

33. Bí a bá po wàrà pọ̀ títí, yóo di òrí àmọ́,bí ó bá pẹ́ tí a ti ń tẹ imú, imú yóo ṣẹ̀jẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ríru ibinu sókè, a máa mú ìjà wá!

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 30