Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 30:20-30 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ìwà obinrin alágbèrè nìyí:bí ó bá ṣe àgbèrè tán, á ṣojú fúrú,á ní “N kò ṣe àìdára kankan.”

21. Àwọn nǹkankan wà tíí mi ilẹ̀ tìtì,ọ̀pọ̀ nǹkan wà tí ilẹ̀ kò lè gbà mọ́ra:

22. ẹrú tí ó jọba,òmùgọ̀ tí ó jẹun yó,

23. obinrin tí ayé kórìíra tí ó wá rí ọkọ fẹ́,ati iranṣẹbinrin tí ó gba ọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.

24. Àwọn nǹkan mẹrin kan wà tí wọ́n kéré ninu ayé,sibẹsibẹ wọ́n gbọ́n lọpọlọpọ:

25. àwọn èèrà kò lágbára,ṣugbọn wọn a máa kó oúnjẹ wọn jọ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.

26. Àwọn ehoro ìgbẹ́ kò lágbára,sibẹsibẹ wọ́n ń kọ́ ilé sí pàlàpálá òkúta.

27. Àwọn eṣú kò ní ọba,sibẹsibẹ wọ́n ń rìn ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.

28. Eniyan lè fi ọwọ́ mú aláǹgbá,sibẹsibẹ wọ́n pọ̀ ní ààfin ọba.

29. Àwọn nǹkan mélòó kan wà tí ìrìn yẹ,àwọn nǹkan pọ̀ tí ìrìn ẹsẹ̀ wọn máa ń wu eniyan:

30. Kinniun, alágbára jùlọ láàrin àwọn ẹranko,kì í sì í sá fún ẹnikẹ́ni.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 30