Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 30:15-25 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Eṣúṣú bí ọmọbinrin meji, ó sì sọ àwọn mejeeji ni:“Mú wá, Mú wá.”Àwọn nǹkan pupọ wà tí kì í ní ìtẹ́lọ́rùn,wọ́n pọ̀ tí nǹkan kìí tó:

16. isà òkú ati inú àgàn,ilẹ̀ tí ń pòùngbẹ omi ati iná,wọn kì í sọ pé, “Ó tó.”

17. Ẹni tí ń fi baba rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́,tí ó kọ̀ tí kò tẹríba fún ìyá rẹ̀,ẹyẹ ìwò àfonífojì ati àwọn igún ni yóo yọ ojú rẹ̀ jẹ.

18. Àwọn nǹkankan wà tí ń jọ mí lójú,àwọn nǹkan mẹrin kò yé mi:

19. ipa ẹyẹ idì ní ojú ọ̀run,ipa ejò lórí àpáta,ọ̀nà tí ọkọ̀ ń tọ̀ lójú òkun,ati nǹkan tí ń bẹ láàrin ọkunrin ati obinrin.

20. Ìwà obinrin alágbèrè nìyí:bí ó bá ṣe àgbèrè tán, á ṣojú fúrú,á ní “N kò ṣe àìdára kankan.”

21. Àwọn nǹkankan wà tíí mi ilẹ̀ tìtì,ọ̀pọ̀ nǹkan wà tí ilẹ̀ kò lè gbà mọ́ra:

22. ẹrú tí ó jọba,òmùgọ̀ tí ó jẹun yó,

23. obinrin tí ayé kórìíra tí ó wá rí ọkọ fẹ́,ati iranṣẹbinrin tí ó gba ọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.

24. Àwọn nǹkan mẹrin kan wà tí wọ́n kéré ninu ayé,sibẹsibẹ wọ́n gbọ́n lọpọlọpọ:

25. àwọn èèrà kò lágbára,ṣugbọn wọn a máa kó oúnjẹ wọn jọ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 30