Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 30:13-25 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Àwọn kan wà tí ojú wọ́n ga,lókè lókè ni ojú wọn wà.

14. Àwọn kan wà tí eyín wọn dàbí idà,kìkì ọ̀bẹ ló kún èrìgì wọn,láti jẹ àwọn talaka run lórí ilẹ̀ ayé,ati láti pa àwọn aláìní run láàrin àwọn eniyan.

15. Eṣúṣú bí ọmọbinrin meji, ó sì sọ àwọn mejeeji ni:“Mú wá, Mú wá.”Àwọn nǹkan pupọ wà tí kì í ní ìtẹ́lọ́rùn,wọ́n pọ̀ tí nǹkan kìí tó:

16. isà òkú ati inú àgàn,ilẹ̀ tí ń pòùngbẹ omi ati iná,wọn kì í sọ pé, “Ó tó.”

17. Ẹni tí ń fi baba rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́,tí ó kọ̀ tí kò tẹríba fún ìyá rẹ̀,ẹyẹ ìwò àfonífojì ati àwọn igún ni yóo yọ ojú rẹ̀ jẹ.

18. Àwọn nǹkankan wà tí ń jọ mí lójú,àwọn nǹkan mẹrin kò yé mi:

19. ipa ẹyẹ idì ní ojú ọ̀run,ipa ejò lórí àpáta,ọ̀nà tí ọkọ̀ ń tọ̀ lójú òkun,ati nǹkan tí ń bẹ láàrin ọkunrin ati obinrin.

20. Ìwà obinrin alágbèrè nìyí:bí ó bá ṣe àgbèrè tán, á ṣojú fúrú,á ní “N kò ṣe àìdára kankan.”

21. Àwọn nǹkankan wà tíí mi ilẹ̀ tìtì,ọ̀pọ̀ nǹkan wà tí ilẹ̀ kò lè gbà mọ́ra:

22. ẹrú tí ó jọba,òmùgọ̀ tí ó jẹun yó,

23. obinrin tí ayé kórìíra tí ó wá rí ọkọ fẹ́,ati iranṣẹbinrin tí ó gba ọkọ mọ́ ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.

24. Àwọn nǹkan mẹrin kan wà tí wọ́n kéré ninu ayé,sibẹsibẹ wọ́n gbọ́n lọpọlọpọ:

25. àwọn èèrà kò lágbára,ṣugbọn wọn a máa kó oúnjẹ wọn jọ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 30