Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 3:2-15 BIBELI MIMỌ (BM)

2. nítorí wọn óo fún ọ ní ẹ̀mí gígùnati ọpọlọpọ alaafia.

3. Má jẹ́ kí ìwà ìṣòótọ́ kí ó fi ọ́ sílẹ̀,so àánú ati òtítọ́ mọ́ ọrùn rẹ,kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ.

4. Nípa bẹ́ẹ̀, o óo rí ojurere ati iyì lọ́dọ̀ Ọlọrun ati eniyan.

5. Fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,má sì tẹ̀lé ìmọ̀ ara rẹ.

6. Mọ Ọlọrun ní gbogbo ọ̀nà rẹ,yóo sì mú kí ọ̀nà rẹ tọ́.

7. Má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n lójú ara rẹ, bẹ̀rù OLUWA, kí o sì yẹra fún ibi.

8. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóo jẹ́ ìwòsàn fún ara rẹ,ati ìtura fún egungun rẹ.

9. Fi ohun ìní rẹ bọ̀wọ̀ fún OLUWApẹlu gbogbo àkọ́so oko rẹ.

10. Nígbà náà ni àká rẹ yóo kún bámúbámú,ìkòkò waini rẹ yóo sì kún àkúnya.

11. Ọmọ mi, má ṣe kẹ́gàn ìtọ́ni OLUWA, má sì ṣe jẹ́ kí ìbáwí rẹ̀ sú ọ.

12. Nítorí ẹni tí OLUWA bá fẹ́ níí báwí gẹ́gẹ́ bí baba tí máa ń bá ọmọ rẹ̀ tí ó bá fẹ́ràn wí.

13. Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó wá ọgbọ́n rí,ati ẹni tí ó ní òye.

14. Nítorí èrè rẹ̀ dáraju èrè orí fadaka ati ti wúrà lọ.

15. Ọgbọ́n níye lóríó ju ohun ọ̀ṣọ́ olówó iyebíye lọ,kò sí ohun tí o lè fi wé e,ninu gbogbo ohun tí ọkàn rẹ lè fẹ́.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 3