Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 3:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọmọ mi, má ṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ọ,sì pa òfin mi mọ́ lọ́kàn rẹ,

2. nítorí wọn óo fún ọ ní ẹ̀mí gígùnati ọpọlọpọ alaafia.

3. Má jẹ́ kí ìwà ìṣòótọ́ kí ó fi ọ́ sílẹ̀,so àánú ati òtítọ́ mọ́ ọrùn rẹ,kọ wọ́n sí oókan àyà rẹ.

4. Nípa bẹ́ẹ̀, o óo rí ojurere ati iyì lọ́dọ̀ Ọlọrun ati eniyan.

5. Fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,má sì tẹ̀lé ìmọ̀ ara rẹ.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 3