Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 29:16-27 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Nígbà tí eniyan burúkú bá wà lórí oyè, ẹ̀ṣẹ̀ a máa pọ̀ síi,ṣugbọn lójú olódodo ni wọn yóo ti ṣubú.

17. Tọ́ ọmọ rẹ, yóo sì fún ọ ní ìsinmi,yóo sì mú inú rẹ dùn.

18. Orílẹ̀-èdè tí kò bá ní ìfihàn láti ọ̀run, yóo dàrú,ṣugbọn ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ń pa òfin mọ́.

19. Ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan kò tó láti fi bá ẹrú wí,ó lè fi etí gbọ́ ṣugbọn kí ó má ṣe ohunkohun.

20. Òmùgọ̀ nírètí ju ẹni tí yóo sọ̀rọ̀ sọ̀rọ̀,tí kò lè kó ara rẹ̀ ní ìjánu lọ.

21. Bí eniyan bá kẹ́ ẹrú ní àkẹ́jù,yóo ya ìyàkuyà níkẹyìn.

22. Ẹni tí inú ń bí a máa dá rògbòdìyàn sílẹ̀,onínúfùfù a sì máa ṣe ọpọlọpọ àṣìṣe.

23. Ìgbéraga eniyan a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀,ṣugbọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn yóo gba iyì.

24. Ẹni tí ó ṣe alábàápín pẹlu olè kò fẹ́ràn ẹ̀mí ara rẹ̀,ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ègún, ṣugbọn kò sọ fún ẹnikẹ́ni.

25. Ìbẹ̀rù eniyan a máa di ìdẹkùn fún eniyan,ṣugbọn ẹni bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA yóo wà láìléwu.

26. Ọ̀pọ̀ ń wá ojurere olórí,ṣugbọn OLUWA níí dáni ní ẹjọ́ òdodo.

27. Olódodo a máa kórìíra alaiṣootọ,eniyan burúkú a sì kórìíra eniyan rere.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 29