Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 27:4-18 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ìkà ni ibinu, ìrúnú sì burú lọpọlọpọ,ṣugbọn, ta ló lè dúró níwájú owú jíjẹ?

5. Ìbáwí ní gbangba sàn ju ìfẹ́ kọ̀rọ̀ lọ.

6. Òtítọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ ẹni lè dunni bí ọgbẹ́;ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìfẹnukonu ọ̀tá.

7. Ẹni tí ó yó lè wo oyin ní àwòmọ́jú,ṣugbọn bí nǹkan tilẹ̀ korò a máa dùn,lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.

8. Ẹni tí ó ṣìnà ilé rẹ̀,dàbí ẹyẹ tí ó ṣìnà ìtẹ́ rẹ̀.

9. Òróró ati turari a máa mú inú dùn,ṣugbọn láti inú ìmọ̀ràn òtítọ́ ni adùn ọ̀rẹ́ ti ń wá.

10. Má pa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tì ati àwọn ọ̀rẹ́ baba rẹ;má sì lọ sí ilé arakunrin rẹ ní ọjọ́ ìṣòro rẹ.Nítorí pé aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni sàn ju arakunrin tí ó jìnnà sí ni lọ.

11. Ọmọ mi, gbọ́n, kí o sì mú inú mi dùn,kí n lè rí ẹnu dá àwọn tí wọn ń pẹ̀gàn mi lóhùn.

12. Amòye eniyan rí ewu, ó sì fi ara rẹ̀ pamọ́,ṣugbọn òpè kọjá lọ láàrin rẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.

13. Gba ẹ̀wù ẹni tí ó bá ṣe onídùúró fún àlejò,kí o sì gba nǹkan ìdógò lọ́wọ́ rẹ̀,tí ó bá ṣe onídùúró fún àjèjì obinrin.

14. Ẹni tí ó jí ní kutukutu òwúrọ̀,tí ó ń fi ariwo kí aládùúgbò rẹ̀,kò yàtọ̀ sí ẹni tí ń ṣépè.

15. Iyawo oníjà dàbí omi òjò,tí ń kán tó! Tó! Tó! Láì dáwọ́ dúró;

16. ẹni tí bá ń gbìyànjú láti dá irú obinrin bẹ́ẹ̀ lẹ́kundàbí ẹni tí ń gbìyànjú láti dá afẹ́fẹ́ dúró,tabi ẹni tó fẹ́ fi ọwọ́ mú epo.

17. Bí irin ti ń pọ́n irin,bẹ́ẹ̀ ni eniyan ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹnìkejì rẹ̀.

18. Ẹni tí ń tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ yóo rí èso rẹ̀ jẹ,ẹni tí ń tọ́jú ọ̀gá rẹ̀ yóo gba ìyìn rẹ̀.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 27