Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 27:21-27 BIBELI MIMỌ (BM)

21. Iná ni a fi ń dán wúrà ati fadaka wò,ìyìn ni a fi ń dán eniyan wò.

22. Wọn ì báà ju òmùgọ̀ sinu odó,kí wọn fi ọmọ odó gún un pọ̀ mọ́ ọkà,ẹnìkan kò lè gba ìwà òmùgọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.

23. Rí i dájú pé o mọ̀ bí agbo ẹran rẹ ti rí,sì máa tọ́jú ọ̀wọ́ ẹran rẹ dáradára;

24. nítorí ọrọ̀ kì í pẹ́ lọ títí,kí adé pẹ́ lórí kì í ṣe láti ìrandíran.

25. Lẹ́yìn tí a bá gé koríko, tí koríko tútù mìíràn sì hù,tí a bá kó koríko tí a gé lára àwọn òkè wálé,

26. o óo rí irun aguntan fi hun aṣọ,o óo sì lè fi owó tí o bá pa lórí àwọn ewúrẹ́ rẹ ra ilẹ̀.

27. O óo rí omi wàrà ewúrẹ́ rẹ fún, tí o óo máa rí mu,ìwọ ati ìdílé rẹ, ati àwọn iranṣẹbinrin rẹ pẹlu.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 27