Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ìwé Òwe 27:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Má lérí nípa ọ̀la,nítorí o kò mọ ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.

2. Ẹlòmíràn ni kí o jẹ́ kí ó yìn ọ́, má yin ara rẹ,jẹ́ kí ó ti ẹnu ẹlòmíràn jáde,kí ó má jẹ́ láti ẹnu ìwọ alára.

3. Òkúta wúwo, yanrìn sì tẹ̀wọ̀n,ṣugbọn ìmúnibínú aṣiwèrè wúwo lọ́kàn ẹni ju mejeeji lọ.

4. Ìkà ni ibinu, ìrúnú sì burú lọpọlọpọ,ṣugbọn, ta ló lè dúró níwájú owú jíjẹ?

5. Ìbáwí ní gbangba sàn ju ìfẹ́ kọ̀rọ̀ lọ.

6. Òtítọ́ ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ ẹni lè dunni bí ọgbẹ́;ṣugbọn ẹ̀tàn ni ìfẹnukonu ọ̀tá.

7. Ẹni tí ó yó lè wo oyin ní àwòmọ́jú,ṣugbọn bí nǹkan tilẹ̀ korò a máa dùn,lẹ́nu ẹni tí ebi ń pa.

8. Ẹni tí ó ṣìnà ilé rẹ̀,dàbí ẹyẹ tí ó ṣìnà ìtẹ́ rẹ̀.

9. Òróró ati turari a máa mú inú dùn,ṣugbọn láti inú ìmọ̀ràn òtítọ́ ni adùn ọ̀rẹ́ ti ń wá.

10. Má pa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tì ati àwọn ọ̀rẹ́ baba rẹ;má sì lọ sí ilé arakunrin rẹ ní ọjọ́ ìṣòro rẹ.Nítorí pé aládùúgbò tí ó súnmọ́ ni sàn ju arakunrin tí ó jìnnà sí ni lọ.

Ka pipe ipin Ìwé Òwe 27